Gírámà èdè Yorùbá: Òrò Atókùn (prepositions)

 Àlàyé lórí Òrò atókùn ń gbé òwe Yorùbá léyìn pé '' bí a bójú tí a bómú, ìsàlè àgbòn làá Parí rè sí ''. Èyìí rí béè nítorí pé ohun tí a pè ní atókùn yìí jo ìsòrí Òrò ìse. Àbùdá Òrò ìse àti Òrò atókùn jora púpò láti fí so pé Òrò ìse ni, sùgbón ìsòrí Òrò tí ó dá dúró ni Òrò atókùn jé.
 Àwon Òrò tí a ń pé ní atókùn ni:

tí, fi, pèlú, ní, láti, fún, bá, sí.

Àwon àpęęrę tó se àlàyé rè fún wa ní wònyìí.

Mo fò sókè Fún ayò
N ó lo sí ojà Ní àìpé.
A wà Ní ibí ó.
Túndé FI èrú gba ìbùkún
Fájémirókun FI owó mo Olorun
Àwon sójà ń TI ojú ogun Sambísa dé.
Alàájì ti dé LÁTI mókà.
Olóyè dé PÈLÚ ìlù àti Ariwo.

Bí a bá se Akíyèsí daada, a ó ri pé ègé kan ni Òrò atókùn máa ń ní, ó máa ń bèrè pèlú kóńsónántì, ó sì máa ń gba àbò. A ó ri wí pé àwon ìrísí àti ìhùwà si rè dá gégé bí Òrò ìse.

Comments

  1. Ni ero temi, Oro-Ise Asokunfa ni "fi". Kii se Oro-Atokun. Lilo re ko yato si ilo:
    1. "mu" ninu = Ore mi mu mi je iya.
    2. "fi" ninu = Sade fi abara kekere gba nla.
    3. "ko" ninu = Deji ko awon obi re sinu wahala.

    Ref: Adewole, L.O. et al (2013) Exam Focus Yoruba. Oju-iwe 96

    ReplyDelete

Post a Comment

Popular posts from this blog

Gírámà èdè Yorùbá; Èyán (Adjective)

Ęwààtoge: Orísirísi fìlà okùnrin ní ilè Yorùbá. Beauty&style (types of caps among Yorùbá men).