Ààbò àti ìlera (Health and Protection). Ààbò Ara-ęni. (self protection)

 Ojú ni alákàn fi ń sórí ni Òrò ààbò ara-ęni. Kójú má ríbi àìjàfara ni oògùn rè. Yorùbá kò fi ààbò ara ęni jáfara rárá. Onírúurú aájò àti oògùn ni Wón fi ń sààbò ara won.

Lára àwon oògùn bęè ni kánàkò èyí tó lè so ìrìnàjò tó lé gba òsán méta òru méta di ojó kan péré láìsí ewu.Nínú aájò fún ààbò náà ni òkígbé, ìfúnpá, àti óńdè. Nígbà míràn,Wón le lo àgbékórùn pèlú dàńsíkí àti fìlà; Egbé nìyęn.

Bí àpęęrę, láyé àtíjó Aláàfin òyó gbó pé oba ìlú kan, ìyen Òkukù ní ìpínlè Òsun ní oògùn púpò. Aláàfin pàse pé kí Ó wá fi Ojú kan òun, bí ó ti dé ààfin ni Wón so fún un pé kí ó jókòó lórí ęní, kò mo pé Wón tí gbé kòtò jínjìn sábé ęní. Bó se jókòó ni ęní jìn fìn-ìn.Ó kégbe ńlá ''hèéè! kíké tó ké, inú yàrá rè ní ààfin rè ló bá ara rè lÓkukù.Egbé nìyęn. Ààbò tó péye ló jé láàárin àwon Yorùbá (Ògúnsínà 2012).
À ó má tè síwájú lósè tí ń bò ire!.

Comments

Popular posts from this blog

Gírámà èdè Yorùbá: Òrò Atókùn (prepositions)

Gírámà èdè Yorùbá; Èyán (Adjective)

Ęwààtoge: Orísirísi fìlà okùnrin ní ilè Yorùbá. Beauty&style (types of caps among Yorùbá men).