Gírámà èdè Yorùbá: Ępón (Adverb)

Èpón ni ęmèwà Òrò ìse gégé bí Èyán ti jé ęmèwà fún Òrò orúko, Ohun tí a pè ní ępón jé orísirísi wúnrèn, èyí tí ó bęęrę láti ęyo Òrò kan dé àpólà Òrò àti gbólóhùn. Nítorí náà èpón pé orísirísi: àwon tí ó jé ęyo Òrò tàbí jù bęè lo, àwon tó ń sáájú Òrò ìse, àti àwon tó ń gbęyìn Òrò ìse.

Èpón ęléyo Òrò:
Àwon ępón tí ó jé ęyo Òrò ni àwon Òrò bíi asògbà: ń, ti, má, máa, yóò

Àti èdà won ní àyísódì: kìí, í, tíì, kò, níí.

Èpón ni àwon Òrò tí a lè pé ní múùdù bí: kúkú, tètè, jàjà, mò-ón-mò, sèsè.

Àwon wònyìí máa ń sáájú Òrò ìse ni. Wón lè tèlé ara won bí ìtumò bá fààyè gba ààtò béè. Fún àpęęrę:

Adé máa tètè wá
Adé kúkú máa tètè wá

Àwon èpón kan lè tèlé Òrò ìse. Bí Òrò ìse yen bá gba àbò, àbò láti dúró ti Òrò ìse gbágbá, kí èpón àgbèyin Òrò ìse wá tèlé àkópò Òrò ìse àti àbò rè.

Mo wá RÍ
Mo ta epo ròbì RÍ
Òrò gírámà kò tún yé mi MÓ
Àwon ępón gbęyìn Òrò ìse kò pò rárá.

Comments

Popular posts from this blog

Gírámà èdè Yorùbá: Òrò Atókùn (prepositions)

Gírámà èdè Yorùbá; Èyán (Adjective)

Ęwààtoge: Orísirísi fìlà okùnrin ní ilè Yorùbá. Beauty&style (types of caps among Yorùbá men).