Ààbò àti ìlera (Health and protection) Taboo!

Ohun pàtàkì tó n mú kí àlàáfíà àti ààbò wà lórí ęní ni èèwò, olúkálùkù ìlú àti Ilé ló ní èèwò tí won, Yorùbá kò fi Òrò èèwò seré rárá, Ohun tí Wón bá pé ní èèwò, a kìí se é. Èyí kéyìí tí kò wò, tí kò dára láti hù ní ìwà ló ń jé èèwò.

Orísirísi ní èèwò; èèwò àìsàn, èèwò awo, èèwò ìbínibí, èèwò kan-n-pá tàbí òran-an-yan, èèwò amęmìígun àti èèwò amáyégún. Pípa àwon èèwò yìí mó jé orísun ààbò àti àlàáfíà ní ilè Yorùbá.

Gégé bí àpęęrę, òkan nínú èèwò àlàáfíà ni pé ''a kìí ję ejò torítorí '' ogbón púpò wà nínú èèwò yìí.  Ìdí ni pé, gbogbo oró ejò orí ló wà, bí ęnìkan bá sì ję orí ejò tí eegun ejò bá sèesì gún lénu tàbí há a lófun, òrun lęrò. A ó ma tè síwájú lósè tí ń bò. Ire ó

Comments

Popular posts from this blog

Gírámà èdè Yorùbá: Òrò Atókùn (prepositions)

Gírámà èdè Yorùbá; Èyán (Adjective)

Ęwààtoge: Orísirísi fìlà okùnrin ní ilè Yorùbá. Beauty&style (types of caps among Yorùbá men).