Gírámà èdè Yorùbá: Òrò Atókùn (prepositions)
Àlàyé lórí Òrò atókùn ń gbé òwe Yorùbá léyìn pé '' bí a bójú tí a bómú, ìsàlè àgbòn làá Parí rè sí ''. Èyìí rí béè nítorí pé ohun tí a pè ní atókùn yìí jo ìsòrí Òrò ìse. Àbùdá Òrò ìse àti Òrò atókùn jora púpò láti fí so pé Òrò ìse ni, sùgbón ìsòrí Òrò tí ó dá dúró ni Òrò atókùn jé. Àwon Òrò tí a ń pé ní atókùn ni: tí, fi, pèlú, ní, láti, fún, bá, sí. Àwon àpęęrę tó se àlàyé rè fún wa ní wònyìí. Mo fò sókè Fún ayò N ó lo sí ojà Ní àìpé. A wà Ní ibí ó. Túndé FI èrú gba ìbùkún Fájémirókun FI owó mo Olorun Àwon sójà ń TI ojú ogun Sambísa dé. Alàájì ti dé LÁTI mókà. Olóyè dé PÈLÚ ìlù àti Ariwo. Bí a bá se Akíyèsí daada, a ó ri pé ègé kan ni Òrò atókùn máa ń ní, ó máa ń bèrè pèlú kóńsónántì, ó sì máa ń gba àbò. A ó ri wí pé àwon ìrísí àti ìhùwà si rè dá gégé bí Òrò ìse.
Comments
Post a Comment