Posts

Showing posts from October, 2018

Folktales (Àló).

Image
Ó ya ó, a tún gbedé o! èyin Ojúlówó Omo Yorùbá o, kíni ìdáhún ti yín o... #ÀàlóYorùbá #Yorùbádùn  #wevaluemoral #Yorùbáculture  #Besttribeever. #weappreciateourculture

Gírámà èdè Yorùbá Òrò orúko tí a sèdá (Derivational Noun).

Image
Ònà tí a lè pín Òrò orúko sí la gbé dúró lósè tó kojá, Ę jé kí a menú ba àwon Òrò orúko kan tó se wí pé a sèdá won ni.  Yàtò sí àwon Òrò orúko tí a ò mo bí Wón se sè, a lè se àtúnro fún Òrò orúko míràn, èyí lè jé jáde láti inú Òrò isé nípa lílo àfòmó tó jé fáwèlì tàbí àpètúnpè kóńsónántì. Fún àpęęrę àfòmó ìbèèrè fáwèlì láti sèdá Òrò orúko. È+pè= èpè Ì+fę = ìfé Ę+bę= èbè Ę+sę= èsè Ì+ję= ìję Ò+pò= òpò Ò+wón=òwón. Àwon Òrò ìsàlè yìí wáyé nípa àpètúnpè kóńsónántì àkókó nínú Òrò ìse. Torí pé Yorùbá kò fààyè gba àsínpò kóńsónántì, a se àfibò fáwèlì (i) pèlú ohùn òkè láti fí pààlà àwon kóńsónántì tí ì bá jé oníbejì. Pí+pè=pípè Fí+fę=fífé Bí+bę=bíbè Sí+sę=sísè Wí+wón=wíwón Sí+sun=sísun...... Ònà míràn tí a tún lè gbà sèdá Òrò orúko ni nípa àpètúnpè kíkún fún Òrò ìse àti àbò rè. Àpęęrę ni Wolé+wolé=woléwolé Paná+paná=panápaná Gbókù+gbókù=gbókùgbókù Kólé+kólé=kólékólé. A ó ma tè síwájú lósè tí ń bò...

Fact about Yorùbá people. (Home Training).

Image
The fact that each society decides what is moral or immoral does not rule out the fact that there are universal morals. These include; respect for elders, hard work, truthfulness,shunning acts like murder, stealing and incest. The Yorùbá people cherish good morals and do not compromise it for any other thing. They believe that the untrained child will eventually sell the house one builds. An aspect of this kind of training is referred to as èkó-ilé (home training). A child, from infancy, is taught the language used for greeting, respect for elders. He learn about myths and taboos, from where he brings out different moral lessons. Akínjógbin.

Òwe Yorùbá (Yorùbá proverbs)

Image
'' if you avoid work, you can't avoid poverty''. Torí náà Múra sísé òré MI. Isé la fi ń dęni gíga. Bí a kò bá r'éni fèhìntì, bí òlę làárí. Bí a kò bá r'éni gbékè lé, a tęra m'ósé ni. #ÒweYorùbá #Yorùbádùn #Wevaluemoral #Weappreciateourculture #Proverbmonday.

Tia ń tia ni. (ìwà lęwà)

Image
Yorùbá bò Wón ní; ìwà lęwà. Iręlę a sì máa mólá yęni. Olorì àná, ti oba Adéyeyè Ęnìtàn Oòni ifè, fi ohun tó ní'ye lórí jùlo ní ilè Yorùbá (ìwà omolúàbí) hàn nínú Òrò tí Wón fi ránsé sáàfin sí oba àti Olorì tuntun.Òrò náà lo báyìí wí pé...  ''it was once said that there is Nobility in Compassion, Beauty in Empathy,and Grace in Forgiveness. Congratulations to the Oòni & his new bride, Shílèkùnola Naomi Morónké Oluwaseyi. May God bless your union''. Ohun tí èyí túmò sí ni pé; ''ìgbéga ń bę nínú fífę Ore fún Omonìkejì, Ęwà si ń bę nínú Ìfomonìyànse, àti wí pé Ore-òfę ń bę nínú Ìdáríjì. Mó kí Oòni àti Olorì rè tuntun Shílèkùnola Naomi Morónké oluwaseyi. Èdùmàrè yóò bùkún ìgbéyàwó yín''. Hmmm.... Ní tòótó ni wí pé Ęwà ń bę nínú ìfomonìyànse mo gbóríyìn fún @hhzaynab.

Health and Protection in Yorùbá land (Ààbò àti ìlera nílè Yorùbá) Herbal drugs.

Image
In spite of western Education and Religions, many homes still make use of àgbo. There are many villages in Yorùbá land where there are no clinics and maternities, in such places the communities rely on traditional birth attendants and traditional medicine men. The use of herbal drugs is an important practice among the Yorùbá people, herbal drugs are in the form of decoction (àgbo), concocted diet (àsèje), body lotion (ìpara), pounded  roots, leaves and barks of tree (àgúnmu), and powdered herbal materials for use either with oil or with water (lúbúlúbú) Olaoye. ''Nearly every home in the traditional society has a store or medicament for various ailments and diseases''. Awolalu. Ire ó!

Ęwà Àtoge (Beauty&Style) nílè Yorùbá.

Image
In the main, the Yorùbá claim to be descendants of a great ancestor. There is no doubt at all, that they have a great race. Indeed, they are the progeny of Great War lords, efficient kingdom builders and astute rulers. They have been enjoying for centuries a well organized pattern of society, a pattern which persists basically in spite of all the changes consequently upon modern contacts with the western world.  Their kings have from a very long past, worn costly beaded crowns and wielded royal scepters. And no one remembers a time when the Yorùbá have not worn clothes. Truly, then, they have their reasons for being proud of their race. Ìdòwú (1955).  Èrí àrígbámú ni pé yàtò sí pé omo akin ni ìran Yorùbá láti ìbèrè ayé won, Wón tún jé omo akoni-lógun, tó mètò tí à á fí tòlú tí fi i tùbà tùsę. Ìjì àyípadà gan-an tó tipasè àjosępò pèlú àwon òyìnbó wáyé kò bí òlàjú àsà ìwoso olówó ìyebíye lóní-ran-ń-ran tí toba tìjòyè ìlú ń wò láti se ęsó, ęwà àtoge sára won. Kò sí tàbí sùgbón...

àló

Image
Ó ya ó, a tún gbedé o! èyin Ojúlówó Omo Yorùbá o, kíni ìdáhún ti yín o #ÀàlóYorùbá #Yorùbádùn  #wevaluemoral #Yorùbáculture  #Besttribeever. #weappreciateourculture

Gírámà èdè Yorùbá (ìsòrí Òrò orúko)..

Image
Gégé bí ibi tí a gbé dúró lósè tó kojá ní wí pé , a lè pín Òrò orúko sí orísirísi ònà, èyí tó ń tóka sí èèyàn, ęranko, nńkan abèmí, nńkan aláìléèmí, àfòyemò, ibi, ònkà, ipò, àti bęè bęè lo. Díè nínú Òrò orúko nípa Ìpín ìsòrí nì yìí; Èèyàn;  Adéwálé, Àgbède, Onílù, Omoge, Olábísí,... Ęranko;  Òyà, Àparò, Erin, Ejo, Ìnàkí, Èèrà,... Aláìléèmí;  Òkúta, Egbò, Igi, Koríko, Ìlù,.. Àfòyemò;  Ogbón, Òótó, Ìfé, Ìjà, Àféfé,.. Ibi;     Ìsolò, Èkó, ìlorin, Odò, ibi,... Ipò;     ìkínní, ìkejì, ìkèta,.... Ònkà;    Òkan, Èjì, Èta,.... Arópó Orúko;  Mo, O, a, Won,...  Ìtúpalè tó gbòòrò ju èyí lo wà níta, sùgbón ohun tí ó se pàtàkì jù ni pé kí a mò ohun tí Òrò Orúko jé, yàtò sí àtúnpín ìsòrí nípa ìtumò.

Fact about Yorùbá people.

Image
Before the coming of Europeans to the shores of Nigeria, each ethnic group had it's own philosophy, the Yorùbá people inclusive. One of the major philosophies of the Yorùbá is moral philosophy, which is basically based on good character training (the spirit of omolúàbí), that is, the mind frame of good behavior in all it's ramifications. To the Yorùbá people, being an omolúàbí means being of good morals, and morality means ÌWÀ. in the view of Abimbola (1975), said      '' ìwà is the most valuable among all other things In the Yorùbá value system''.  Therefore Good character (ìwà omolúàbí) forms the basis for the Yorùbá traditional educational system known as ètò èkó àbílè.
Image
Yorùbá bò Wón ní..Lówo lówe laalú ìlú agidìgbo, ológbón nìí jo, òmòràn nìí sí mòón. Ę wòye sí òwe yìí ó  #Yorùbádùn  #ÒweYorùbá #wevaluemoral #Yorùbáculture  #Besttribeever. #weappreciateourculture

Tia n tia ni ''Ako ladé orí aya'' (A man is the crown of a wife).

Image
Kábíyèsí oba Aláyélúwà Òòni Adéyeyè Ęnìtàn Babátúndé ogúnwùsì Ojaja kejí Àgbàlagbà òrìsà Àrólé Oòduà Omo Òjajà fìdí òtè jálè Omo ayí kiti ògún Omo etíri Ògún Ajere abojú jojo Ká'dé ó pé lórí, ká'se ó pé lénu kárin-kése. @ooniadimulaife kí aręwà Olorì Shílèkùnola, Morónké Naomi @oluwaseyinaomi káàbò sáàfin,  Baba wí pé, ''I waited patiently upon the almighty the king of kings,he eventually did it in the midst of many trials. Shílèkùnola, Morónké Naomi; the greatest arsenal you can apply on this highly revered throne with many rules and regulations in the midst of undiluted traditional, heritage and culture is the ''fear of God in you'', which is the beginning of your wisdom on this throne of oduduwa. You are welcome home my beautiful and adorable queen''. Ohun tí oba ń so lénu kan ni wí pé ''Mo ni ìfarabalè àti sùúrù fún Elédùmarè oba àwon Oba, Ó sì se é láàárin òpòlopò ìgbìyànjú.'' baba tè síwájú láti gba Olorì ní ìmòràn wí pé...

Ààbò àti ìlera (Health and protection) Yorùbá traditional medicine.

Image
Health care system has been known in the Yorùbá land before the coming of the Europeans. In the olden days, the traditional medicine was highly valued and adopted among the Yorùbás. According to Awolalu, traditional medicine is the art of using the available forces of nature to prevent diseases and to restore and preserve health. The Yorùbá people have a way of rescuing themselves from various available diseases through the use of herbs, powerful, mysterious or potent words, animal parts, living and non living things, water, fasting, prayers, and other rituals of restoration of the harmony among the people and the environment. Before the introduction of western medicine, the oníségùn (physician), occupied an important place in the society. This is because the traditional medicine was the only available source of healing diseases and it was effectively used in the society.

Contemporary Music with Yorùbá Lyrics.

Image
Gégé bí a ti mo wí pé òdú ni @official9ice kìí se àìmò fólóko ní bi ká korin, Orin to kún fún èdè àbínibí Yorùbá, òkan gbòógì ní ó jé nínú àwon ojúlówó Omo Yorùbá tí ń fí èdè Yorùbá yangàn nínú Orin rè. Kò sí Tàbí sùgbón níbè wí pé ká korin tó kún fún èdòki Òrò Yorùbá tàbí ká korin tó ń gbásà àti èdè Yorùbá láruge, Orin tó mógbón wa, Orin tí ń kóni léèkó, ti ń kóni lèdè àbínibí, ìwà omolúàbí àti ìbára-eni-gbé-pò láwùjo, Ęni tí ìrònú rè bá jinlè tí opolo rè sí pé ni a lè gbó irú àwon Orin wònyìí, Torí wí pé àtàrí àjànàkú ni isé Orin kíko, kìí se erù omodé. Òpòlopò Orin ni @official9ice ti ko tó kún fún Òrò ìjìnlè Yorùbá, sùgbón àwon èyí tó wa ní àrówótó wa lè ń gbó yìí, kò sí ani-àní wí pé omo Òduà tokàntokàn ní @official9ice Èdùmàrè yóò tún bò máa ràn yín lówó, opolo yín kò ní jóbà, iwájú iwájú lè ó ma lo. Ire ó!

ìdáhún sí ìbéèrè Àló

Image
Èyin èyán wa àtàtà, ìdáhún sí ìbéèrè wa re oo #ÀàlóYorùbá #Yorùbádùn  #wevaluemoral #Yorùbáculture  #Besttribeever. #weappreciateourculture

Ęwà àtoge (Àsà ìwoso okùnrin nílè Yorùbá) Beauty&style.

Image
Gégé bí a ti so lósè to kojá wí pé, òdú ni Òrò ęwà àtoge síse jé ní ìran Yorùbá kìí se àìmò fólóko won, sáájú kí òlàjú àwon òyìnbó tó wo àwùjo Yorùbá ni wón tí ní orísirísi ònà tí wón gbà sęwà àtoge láàárin tèwe tàgbà, Okùnrin àti obìnrin, Ojúùwòye won ní pa oge síse àtęwà síse ní pé 'ìrínisí ni ìseni lójò àti wí pé bí èèyàn bá se mo ìtójú ara rè se ní yóò se mo ìtójú nńkan rè se sí.     Kò sí tàbí sùgbón níbè wí pé Yorùbá jé ìran tó ní afínjú, Wón gbáfé, àti wí pé won kò sí fojú rénà àsà ìwoso won. Bí a bá ń so ní pa ká soge láàárin àwon okùnrin ní ilè Yorùbá, kìí se ohun tó níye lórí lo títí, Torí Yorùbá gbà wí pé alàì-ní-nńkan se okùnrin níì má ń jí gbó toge.  Fún Ìdí èyí orísi aso tí okùnrin ní nílè Yorùbá kò ju Mérin péré lo, Àwon ni Sòkòtò, Bùbá, Agbádá àti Fìlà. A ó ma tè síwájú lósè tí ń bò. Ire ó!

folktales in Yorùbá.

Image
    Ó ya! èyin Ojúlówó Omo Yorùbá o, kíni ìdáhún ti yín o                                       #ÀàlóYorùbá #Yorùbádùn  #wevaluemoral #Yorùbáculture  #Besttribeever. #weappreciateourculture

Gírámà, Ìsòrí Òrò lèdè Yorùbá. (word classification)

Image
A, BI, DI, E, Ę, FI, GI, GBE, HI, I, JE, KI, LI, MI, NI, O, O, P, RI, SI, SHI, TI, U, WI, YI. A lérò wí pé gbogbo wa ni à ti mo àwon ìró fáwèlì àti kóńsónántì wònyìí?, láì ní fàkókò sòfò mó, Ę jé kí a fi sókàn wí pé èkòó èdè gba ogbòn àti ìfarabalè. Ohun tí à ó máa Se àgbéyèwò lóní ni Àwon Ìsòrí Òrò tí a ní, Ní èdè Yorùbá. Àwon òjògbón ti se ìwádìí dé bi pé ìsòrí Òrò méfà péré ni Wón ní ó wà fún èdè Yorùbá, àwon ìsòrí tí Wón fi lélè tí à ó sì máa tèlé nínú ìdánilékòó yìí ni.. Òrò-orúko --- àpęęrę ni.. Adé, igi, èèrà, ìjà, omo, adìę..... Òrò-ìse --- àpęęrę ni... Wá, lo, pé, tà, rà, dára, fò,..... Èyán --- àpęęrę ni... Púpò, náà, yìí, gan-an,.... Ępón --- àpęęrę ni.... Yóò, ń, ti, kúkú,.... Àsopò --- àpęęrę ni... Àti, sùgbón, tàbí,..... Atókùn --- àpęęrę ni.... Sí, tí, ní,.....        Ę  jé kí a wo Òrò-orúko; Òrò-orúko jé èyíkéyìí Òrò tí ó bá ń so Nnkan kan lórúko, yálà ohun náà lèmí tàbí kò lémi,  àpęęrę díè ni.. Omi, tábìlì, ifá, òyìnbó, ajá,...

Fact you need know about the Yorùbá people.

Image
The Yorùbá people constitute one of the major ethnic groups in modern Nigeria with estimated population to be over thirty Million and majority of them reside at their traditional homeland, south western part of the country (Nigeria).  They are found in the present States of Òyó, Ògùn, Òsun, Òndò, Èkìtì, Lágòs and some parts of kwárà and kogí State. The sub ethnic groups found in Yorùbá land are; Ìjèsà, Ìjèbú, Òyó, Ifè, Òndò, Àkókó, Èkìtì, Ìkálè, Ìlaje, Ègbádò, Okun, and Ìgbómínà. There is a considerable population of Yorùbá migrants in Northern and South Eastern parts of Nigeria. A large number of Yorùbá people inhabit the republic of Benin, Togo and some west African countries, in addition Yorùbá diaspora are also found in Europe, North and South America,Brazil, Cuba, Trinidad and the Caribbean island....

Happy Birthday to ikú bàbá yèyé, Oba Adéyemí Aláàfin of òyó.

Image
Àtàndá òòsà, A gbó sá sá má sàá , irúmolè tí ń gbé'nú ààfin , ikú bàbá yèyé, Aláse, èkèjì òrìsà,  òrìsà baba Àkèé , òòsà Oko túnráyò, oko Ojúolápé, Oko Adébímpé baba làtífátù, Àtàndá Omo pópó,  Oba lomo Adéyemí,  Omo ikú, Omo àrùn! Òkòtó aníyìkáyé olórí Oba. Adé á pé lórí,  Àse á pé lénu,  igba odún, ìséjú kan ni.  E dá músò o!!!

òwe ojó ajé (Monday proverb)

Image
 Who do evil in secret, if an earthly king does not see you, the heavenly king sees you.(Literal meaning) Every act of man will be judge accordingly, as no evil doer Will go unpunished. (philosophical meaning). This proverb preaches godliness and honesty. It also condemns stealing in strong terms, affirming that Almighty God is all knowing, it's clearly shown that Yorùbá social values rest firmly on good conducts such as revealed in both their literal and philosophical meanings.       The major communicative function of proverbs in any culture is to teach (moral) lessons through the sociocultural norms, values and the general worldview of a people, it is through proverbs that the rich Africa cultural values can be best evaluated.  This is obvious in an Igbo proverb which says '' anyone who needs interpretation of the proverbs used for him, his mother's dowry is a waste'' The above cited proverb shows the degree of importance that African socie...

Tia tia ni (Jíjé orúko tó ní ìtumò).

Image
Yorùbá bò Wón ní, 'a so Omo ní sódé, Omo lo àjò Ó dé, a so Omo ní sóbò, Omo ràjò ó bò, a wá so Omo ní Sórìnlo, omo ràjò kò dé, ta ni kò mò pé Ilé ni omo ti mú orúko anù lo? Ní tòótó ni wí pé orúko Omo níí ro omo, orúko ęní sì ní ìjánu ęní. Jíjé orúko tó ní ìtumò jé ohun tí ìran Yorùbá káràmáàsíkí púpò, won kan kìí sàdédé fún Omo lórúko. Ní ilè Yorùbá àwon ìsèlè tó bá selè lásìkò tí Wón bímo tàbí ohun tó bá rò mó bí Omo se wáyé lásìkò ìbímo ni wón wò kó tóó so Omo lórúko.  Ìdí nìyìí tí Yorùbá fi wí pé 'òòró Ilé, ibú Ilé, làá wò ká tóó somo lórúko. Ìyí túmó sí wí pé kò sí orúko tí kò ní ìtumò nílé Yorùbá. A ó ma tè síwájú lósè tí ń bò.  Ire ó!

Ààbò àti Ìlera ní ilè Yorùbá (Protection and health in Yorùbá society)

Image
Láti ìgbà táyé ti ń jáyé ni ìran Yorùbá ti jé ìran tó fi àlàáfíà àti ààbò tó péye se ìpìlè Ilé, ìlú, àti àwùjo won. Ìbéèrè tó wúlò ni pé; kí ni won fi ń se é? Báwo nì won se ń se é?. Láti ìgbà ìwásè ni Yorùbá tí jé ìran amèètò -sèètò, amètòrsètór, amo-ire-se-ire àti omolúàbí. Nínú gbogbo abala ìsèlù, ìbara-eni-gbé-pò, ìmò-ìjìnlè-èrò àti Òrò esìn, kò sí èyí tí won kò gbé kalè létòlétò. tipétipé sì ni ètò won tí so mó Òrò ààbò àti ìlera. Yorùbá kò fi owó yepere mú Òrò ààbò, Wón sì ní ètò ààbò tó kira bí Ààbò Ara-ęni, ààbò Ilé, ààbò isé, ààbò àdúgbò àti ààbò ìlú.         Ààbò Ara-ęni. Ojú ni alákàn fi ń sórí ni Òrò ààbò ara-ęni. Kójú má ríbi àìjàfara ni oògùn rè. Yorùbá kò fi ààbò ara ęni jáfara rárá. Onírúurú aájò àti oògùn ni Wón fi ń sààbò ara won. Lára àwon oògùn bęè ni kánàkò èyí tó lè so ìrìnàjò tó lé gba òsán méta òru méta di ojó kan péré láìsí ewu.Nínú aájò fún ààbò náà ni òkígbé, ìfúnpá, àti óńdè. Nígbà míràn,Wón le lo àgbékórùn pèlú dàńsík...

Contemporary music with Yorùbá lyrics (Orin ìgbàlódé tó kún fún èdè Yorùbá)

Image
Láti ìgbà tí Olódùmarè ti sèdá ènìyàn ni ó ti fún won ní ohùn àti ogbòn ìlò ohùn láti máa fi èrò inú won han elòmíràn, yóò tètè yé wa irú ipò pàtàkì tí ìlò ohùn kó ní àwùjo. Bí àwùjo kan bá jé àwùjo sòròsòrò bí i ti Yorùbá, a óò rii pé láti ilè pèpè ni Olódùmarè tí fún won ní irin isé Òrò siso. Ó ro àwon Yorùbá lórùn púpò láti máa fi Òrò enu won àti ohùn won dá orísirísi àrà láti fí èrò inú won hàn, kò sí itú tí won ń fi èdè pa, yálà nínú Òrò geere, nínú ewì tàbí Orin kíko.   Akíyèsí wa ni wí pé kí èèyàn tó lè korin tó mógbón wa tàbí ko Orin tí ń kóni léèkó,yálà èkó èdè ni, ìwà omolúàbí, àsà tàbí orin ìláforítì a.b.b.l. Ó gbúdò jé eni tó ní ìrònú tó jinlè tí opolo rè sí pé dáada. Torí wí pé àtàrí àjànàkú ni isé Orin kíko, kìí se erù omodé. Ìdí nìyìí tí a fi gbé abala yìí kalè láti máa gbóríyìn fún àwon akorin tí ń ló èdè àbínibí Yorùbá nínú Orin won. Olórin tí à ó máa Se àgbéyèwò orin rè lóní ni @qdot_alagbe. Tí a bá ń so ní pa ká korin tó kún fún èdòki Òrò Yorùbá tàbí kí a kori...

Ęwà Àtoge (Beauty and style).

Image
Kò sí àní-àní wí pé ìran Yorùbá jé òkan nínú àwon ìran ènìyàn tó lajú jù lóde ayé yìí, ìran tó láfínjú, Wón gbáfé àti pàápàá ìran tó ríran róokán. Yorùbá kìí se ìran tó se fowó ró séhìn ní bi ká sara lóge àti ká sęwà sára, ogbón ęwà síse àtoge síse ní àwujo Yorùbá dá won lójú tó fi jé wí pé ibikíbi tí Wón bá wà gbogboogbo lowó ń yo jù orí ni Òrò won máa ń jé. Ní tòótó, 'òrun losùpá ti múyì wáyé' ni Òrò ęwà àtoge síse jé ní ìran Yorùbá Ìdí ni yìí tí ònà ìgbàsoge won fi máa ń peléke ní bi ká woso tó bá ìgbà mu, ká sojú lóge, gèlè wíwé tàbí agbádá wíwò ní ònà àrà tó jojú, fífi ilèkè lórísirísi dábírà ęwà sára, kàá woso tó buyì kún ni láwùjo nínú ìran Yorùbá ló pèkun sí. Yorùbá ní, a sá kéké ogún, a bàbàjà ogbòn, a se sòbòrò ló yęjú Áájò ęwà náà ni gbogbo rè, Abala yìí ni à ó ti máa se àfihàn onírùrúurú ònà tí a ń gbà se Oge àti ęwà sára láwùjo wa lóòní pàápàá jùlo láàárin àwon obìnrin wa, tí a o sí ma se àfihàn àwon Omo Yorùbá tí Wón séni lóge, àwon asoge tà (models) àt...

Ìdáhún sí ìbéèrè wa re o, Ekú ilakáì #ÀàlóYorùbá #Yorùbádùn #wevaluemoral #Yorùbáculture

Image

Ìfáàrà sí gírámà èdè Yorùbá.

Image
Ó se pàtàkì kí a mò wí pé kìí se pé a ń gbé elédè jókòó láti kó ní èdè rè, Torí Elédùmarè ti da èdè mó Èèyàn bí ó ti dá mèéè mó àgùntàn, tí ó sì dá kekeréńke mó akùko. Eyìí ni pe èèyàn mú ìmò èdè wá látòrun ni, ìmò àbínibí yìí ni èèyàn fi ń jé èèyàn, gbogbo  èdè la lè so sùgbón eyìí tí aládùgbò wa bá gbó ni a ń so nígbèyìn. Ìdí nìyìí tí Omo Yorùbá tí a bí ní ìlú òyìnbó yóò fi gbó Gèésì bí oba ìlú Èèbó. Béè sì ni Omo Hawusa tí a bí ní Ilé-ifè yóò lè so Yorùbá bí Omo Ooni. Ìdí nìyìí tí ó fi jé pé bí omodé bá ń dàgbà láàárin orísirísi èyà yóò gbó òpò èdè. Ohun tí a o gbájú mó níbí abala yìí ni ohun tí elédè gbudò mò kí a tó so pé ó gbó èdè náà. Nnkan yìí lè jé àtòpò Ìrò ní ìbámu pèlú ìlànà kan pàtó, Ó lè jé àtòpò orísirísi Òrò, Ó sì lè jé orísi ìtumò ti àtòpò ìró ohùn tàbí àtòpò Òrò ní.    Ìmò èdè jé ìmò nípa ìró, Òrò àti ìtumò won nínú àtòpò. Ní ònà míràn èwè, ìmò èdè tí a ń pé ní gírámà pín sí orísi méta pàtàkì;  ìró ohùn (ìmò fònétíìkì), àtòpò Òrò (ìmò sínt...

Yorùbá folktales.

Image
Ó ya! èyin Ojúlówó Omo Yorùbá o, kíni ìdáhún ti yín o #ÀàlóYorùbá #Yorùbádùn  #wevaluemoral  #Yorùbáculture  #Besttribeever. #weappreciateourculture  Wednesdays are for folktales and Yorùbá grammar 😉

Fact about Yorùbá people.

Image
Unlike the theory of evolution, the Yorùbá people strongly believe in Olódùmarè (God almighty),who created and knows all things. Yorùbá people are fairly popular for their pragmatic approach to both fundamental and basic issues of life. Although, Yorùbá speaking people can be found in places like republic of Benin, Brazil, Cuba, and America amongst others; they are predominantly settled in the south -western part of Nigeria. While the Yorùbá people believe strongly in their culture heritage and it also serves as their identity.

The place of proverbs among the Yorùbá people.

Image
Proverbs are reflections and expressions of wisdom, ethics, philosophy and beliefs of a given society. Yorùbá proverbs are treasured sayings, which project the wisdom, ethics, cultural heritage  and worldview of the Yorùbá people. They are used to accentuate a given idea or an outlook to life generally. They also add glamour and Beauty to discourse whether spoken or written in any given circumstance. Proverbs are words of wisdom expressed in concise statements. They are repository words of wisdom, and elders are they custodians of them. Proverbs are therefore a vital instrument of communication in interpersonal relationships. They are important and relevant socially,  religiously, culturally, politically and in other areas; not only to literature, but also to the mass media; who display it in their cartoons, advertisement and film. Òjó (2015,p.4) Olátúnjí (1984,p.172) further emphasis on the place of proverbs among the Yorùbá people. He explains that 'Among the Yorùbá, p...

Don't be a chameleon!

Image
Ęni tí Ó bá jé òsákálá, kó jé òsákálá, Ęni tí Ó bá jé òsokolo, kí Ó jé òsokolo; òsákánsoko kò yę Omo ènìyàn.

Let appreciate our language by speaking it.

Image
Because of our rich culture an external jealousy emerged. Now they decided to create an incurable snags for our language with the objective of  apprehending the internal mind of the speakers. now our children can no  longer use the language correctly without the interception of what i call language perpetrators. save our language from death. use it and speak. yoruba language is the best language to pass knowledge.  we are systematized and configured to their language and culture. now the implications are the condemnable atrocities in our cultural and societal system. our children have been mesmerised by this imposition of this language. we are rich and wealthier than this in thought and values. the more you use their killing language the more you sell your identity. we belong to the culture that respects humanity and  places value on naturalisticism. we are god of culture by exhibition. we are black. we are lovers of love. we are value transmitters. we are giver...

ẹ rántí àtunbọ̀tán

Image
Gbogbo ẹ̀yin ò tafà sókè yídó borí Ẹ ò sì semẹ̀dọ̀ sewé agbéjẹ́ mọ́wọ́ Kẹ́ ẹ rántí ọjọ́ àtisun, kí ẹ rántí àtunbọ̀tán

ojúlarí

Image
OJÚLARÍ Ojú ò ṣe fi mọ̀ ìwà ẹ̀dá, Inú ẹ̀dá ò dàbí òde, Bí ẹ bá rí ènìyàn,  ẹ sọ́ra fún wọn Ẹni a ba ñ bárìn ká fura si, Ẹni a bá fura sí ka yẹra fún wọn Torí Ojú wa ko Ojú, ẹsẹ̀ wa ko ẹsẹ̀, Ọwọ́ wa bọwọ́ Ṣùgbọ̀n Inú wa o konú, Oníkùn ló mọ ìkà.

Kò séni m'èdè Àyàn, bí ęni ń sán omele. Tàbí, Kò séni m'èdè Àyàn bí Ó sęni mú kòngó ìlú lówó.

Image

Èyí ni ìjáde fún àyájó ojó òmìnira orílè èdè Nàìjírìá..

Testing

Image
Òwe Yorùbá fún eni bá létí