Tia tia ni (Jíjé orúko tó ní ìtumò).


Yorùbá bò Wón ní, 'a so Omo ní sódé, Omo lo àjò Ó dé, a so Omo ní sóbò, Omo ràjò ó bò, a wá so Omo ní Sórìnlo, omo ràjò kò dé, ta ni kò mò pé Ilé ni omo ti mú orúko anù lo? Ní tòótó ni wí pé orúko Omo níí ro omo, orúko ęní sì ní ìjánu ęní.

Jíjé orúko tó ní ìtumò jé ohun tí ìran Yorùbá káràmáàsíkí púpò, won kan kìí sàdédé fún Omo lórúko. Ní ilè Yorùbá àwon ìsèlè tó bá selè lásìkò tí Wón bímo tàbí ohun tó bá rò mó bí Omo se wáyé lásìkò ìbímo ni wón wò kó tóó so Omo lórúko.
 Ìdí nìyìí tí Yorùbá fi wí pé 'òòró Ilé, ibú Ilé, làá wò ká tóó somo lórúko. Ìyí túmó sí wí pé kò sí orúko tí kò ní ìtumò nílé Yorùbá.
A ó ma tè síwájú lósè tí ń bò.
 Ire ó!

Comments

Popular posts from this blog

Gírámà èdè Yorùbá: Òrò Atókùn (prepositions)

Gírámà èdè Yorùbá; Èyán (Adjective)

Ęwààtoge: Orísirísi fìlà okùnrin ní ilè Yorùbá. Beauty&style (types of caps among Yorùbá men).