Contemporary Music with Yorùbá Lyrics.
Gégé bí a ti mo wí pé òdú ni @official9ice kìí se àìmò fólóko ní bi ká korin, Orin to kún fún èdè àbínibí Yorùbá, òkan gbòógì ní ó jé nínú àwon ojúlówó Omo Yorùbá tí ń fí èdè Yorùbá yangàn nínú Orin rè.
Kò sí Tàbí sùgbón níbè wí pé ká korin tó kún fún èdòki Òrò Yorùbá tàbí ká korin tó ń gbásà àti èdè Yorùbá láruge, Orin tó mógbón wa, Orin tí ń kóni léèkó, ti ń kóni lèdè àbínibí, ìwà omolúàbí àti ìbára-eni-gbé-pò láwùjo, Ęni tí ìrònú rè bá jinlè tí opolo rè sí pé ni a lè gbó irú àwon Orin wònyìí, Torí wí pé àtàrí àjànàkú ni isé Orin kíko, kìí se erù omodé.
Òpòlopò Orin ni @official9ice ti ko tó kún fún Òrò ìjìnlè Yorùbá, sùgbón àwon èyí tó wa ní àrówótó wa lè ń gbó yìí, kò sí ani-àní wí pé omo Òduà tokàntokàn ní @official9ice
Èdùmàrè yóò tún bò máa ràn yín lówó, opolo yín kò ní jóbà, iwájú iwájú lè ó ma lo. Ire ó!
Comments
Post a Comment