Gírámà èdè Yorùbá Òrò orúko tí a sèdá (Derivational Noun).


Ònà tí a lè pín Òrò orúko sí la gbé dúró lósè tó kojá,
Ę jé kí a menú ba àwon Òrò orúko kan tó se wí pé a sèdá won ni.
 Yàtò sí àwon Òrò orúko tí a ò mo bí Wón se sè, a lè se àtúnro fún Òrò orúko míràn, èyí lè jé jáde láti inú Òrò isé nípa lílo àfòmó tó jé fáwèlì tàbí àpètúnpè kóńsónántì.

Fún àpęęrę àfòmó ìbèèrè fáwèlì láti sèdá Òrò orúko.

È+pè= èpè
Ì+fę = ìfé
Ę+bę= èbè
Ę+sę= èsè
Ì+ję= ìję
Ò+pò= òpò
Ò+wón=òwón.

Àwon Òrò ìsàlè yìí wáyé nípa àpètúnpè kóńsónántì àkókó nínú Òrò ìse. Torí pé Yorùbá kò fààyè gba àsínpò kóńsónántì, a se àfibò fáwèlì (i) pèlú ohùn òkè láti fí pààlà àwon kóńsónántì tí ì bá jé oníbejì.

Pí+pè=pípè
Fí+fę=fífé
Bí+bę=bíbè
Sí+sę=sísè
Wí+wón=wíwón
Sí+sun=sísun......

Ònà míràn tí a tún lè gbà sèdá Òrò orúko ni nípa àpètúnpè kíkún fún Òrò ìse àti àbò rè. Àpęęrę ni

Wolé+wolé=woléwolé
Paná+paná=panápaná
Gbókù+gbókù=gbókùgbókù
Kólé+kólé=kólékólé.

A ó ma tè síwájú lósè tí ń bò...

Comments

Post a Comment

Popular posts from this blog

Gírámà èdè Yorùbá: Òrò Atókùn (prepositions)

Gírámà èdè Yorùbá; Èyán (Adjective)

Ęwààtoge: Orísirísi fìlà okùnrin ní ilè Yorùbá. Beauty&style (types of caps among Yorùbá men).