Ààbò àti Ìlera ní ilè Yorùbá (Protection and health in Yorùbá society)


Láti ìgbà táyé ti ń jáyé ni ìran Yorùbá ti jé ìran tó fi àlàáfíà àti ààbò tó péye se ìpìlè Ilé, ìlú, àti àwùjo won. Ìbéèrè tó wúlò ni pé; kí ni won fi ń se é? Báwo nì won se ń se é?. Láti ìgbà ìwásè ni Yorùbá tí jé ìran amèètò -sèètò, amètòrsètór, amo-ire-se-ire àti omolúàbí. Nínú gbogbo abala ìsèlù, ìbara-eni-gbé-pò, ìmò-ìjìnlè-èrò àti Òrò esìn, kò sí èyí tí won kò gbé kalè létòlétò. tipétipé sì ni ètò won tí so mó Òrò ààbò àti ìlera. Yorùbá kò fi owó yepere mú Òrò ààbò, Wón sì ní ètò ààbò tó kira bí Ààbò Ara-ęni, ààbò Ilé, ààbò isé, ààbò àdúgbò àti ààbò ìlú.





       Ààbò Ara-ęni.
Ojú ni alákàn fi ń sórí ni Òrò ààbò ara-ęni. Kójú má ríbi àìjàfara ni oògùn rè. Yorùbá kò fi ààbò ara ęni jáfara rárá. Onírúurú aájò àti oògùn ni Wón fi ń sààbò ara won. Lára àwon oògùn bęè ni kánàkò èyí tó lè so ìrìnàjò tó lé gba òsán méta òru méta di ojó kan péré láìsí ewu.Nínú aájò fún ààbò náà ni òkígbé, ìfúnpá, àti óńdè. Nígbà míràn,Wón le lo àgbékórùn pèlú dàńsíkí àti fìlà; Egbé nìyęn.Bí àpęęrę, láyé àtíjó Aláàfin òyó gbó pé oba ìlú kan, ìyen Òkukù ní ìpínlè Òsun ní oògùn púpò. Aláàfin pàse pé kí Ó wá fi Ojú kan òun, bí ó ti dé ààfin ni Wón so fún un pé kí ó jókòó lórí ęní, kò mo pé Wón tí gbé kòtò jínjìn sábé ęní. Bó se jókòó ni ęní jìn fìn-ìn.Ó kégbe ńlá ''hèéè! kíké tó ké, inú yàrá rè ní ààfin rè ló bá ara rè lÓkukù.Egbé nìyęn. Ààbò tó péye ló jé láàárin àwon Yorùbá (Ògúnsínà 2012).
À ó má tè síwájú lósè tí ń bò ire!.

Comments

Popular posts from this blog

Gírámà èdè Yorùbá: Òrò Atókùn (prepositions)

Gírámà èdè Yorùbá; Èyán (Adjective)

Ęwààtoge: Orísirísi fìlà okùnrin ní ilè Yorùbá. Beauty&style (types of caps among Yorùbá men).