Ęwà Àtoge (Beauty and style).

Kò sí àní-àní wí pé ìran Yorùbá jé òkan nínú àwon ìran ènìyàn tó lajú jù lóde ayé yìí, ìran tó láfínjú, Wón gbáfé àti pàápàá ìran tó ríran róokán. Yorùbá kìí se ìran tó se fowó ró séhìn ní bi ká sara lóge àti ká sęwà sára, ogbón ęwà síse àtoge síse ní àwujo Yorùbá dá won lójú tó fi jé wí pé ibikíbi tí Wón bá wà gbogboogbo lowó ń yo jù orí ni Òrò won máa ń jé.

Ní tòótó, 'òrun losùpá ti múyì wáyé' ni Òrò ęwà àtoge síse jé ní ìran Yorùbá Ìdí ni yìí tí ònà ìgbàsoge won fi máa ń peléke ní bi ká woso tó bá ìgbà mu, ká sojú lóge, gèlè wíwé tàbí agbádá wíwò ní ònà àrà tó jojú, fífi ilèkè lórísirísi dábírà ęwà sára, kàá woso tó buyì kún ni láwùjo nínú ìran Yorùbá ló pèkun sí.

Yorùbá ní, a sá kéké ogún, a bàbàjà ogbòn, a se sòbòrò ló yęjú Áájò ęwà náà ni gbogbo rè, Abala yìí ni à ó ti máa se àfihàn onírùrúurú ònà tí a ń gbà se Oge àti ęwà sára láwùjo wa lóòní pàápàá jùlo láàárin àwon obìnrin wa, tí a o sí ma se àfihàn àwon Omo Yorùbá tí Wón séni lóge, àwon asoge tà (models) àti àwon asojú lóge. Báyé bá ń yí, ę jé ká máa Báyé yí, aso ìgbà làá dá fún ìgbà, ìgbà kan ò ló Ilé ayé gbó.  A ó ma tè síwájú lósè tí ń bò. Ire ó!.

Comments

Popular posts from this blog

Gírámà èdè Yorùbá: Òrò Atókùn (prepositions)

Gírámà èdè Yorùbá; Èyán (Adjective)

Ęwààtoge: Orísirísi fìlà okùnrin ní ilè Yorùbá. Beauty&style (types of caps among Yorùbá men).