Gírámà, Ìsòrí Òrò lèdè Yorùbá. (word classification)

A, BI, DI, E, Ę, FI, GI, GBE, HI, I, JE, KI, LI, MI, NI, O, O, P, RI, SI, SHI, TI, U, WI, YI.

A lérò wí pé gbogbo wa ni à ti mo àwon ìró fáwèlì àti kóńsónántì wònyìí?, láì ní fàkókò sòfò mó, Ę jé kí a fi sókàn wí pé èkòó èdè gba ogbòn àti ìfarabalè. Ohun tí à ó máa Se àgbéyèwò lóní ni Àwon Ìsòrí Òrò tí a ní, Ní èdè Yorùbá.
Àwon òjògbón ti se ìwádìí dé bi pé ìsòrí Òrò méfà péré ni Wón ní ó wà fún èdè Yorùbá, àwon ìsòrí tí Wón fi lélè tí à ó sì máa tèlé nínú ìdánilékòó yìí ni..

Òrò-orúko --- àpęęrę ni.. Adé, igi, èèrà, ìjà, omo, adìę.....

Òrò-ìse --- àpęęrę ni... Wá, lo, pé, tà, rà, dára, fò,.....

Èyán --- àpęęrę ni... Púpò, náà, yìí, gan-an,....

Ępón --- àpęęrę ni.... Yóò, ń, ti, kúkú,....

Àsopò --- àpęęrę ni... Àti, sùgbón, tàbí,.....

Atókùn --- àpęęrę ni.... Sí, tí, ní,.....

       Ę  jé kí a wo Òrò-orúko;

Òrò-orúko jé èyíkéyìí Òrò tí ó bá ń so Nnkan kan lórúko, yálà ohun náà lèmí tàbí kò lémi,  àpęęrę díè ni.. Omi, tábìlì, ifá, òyìnbó, ajá, ìwé, ewúré, síbí, òòyà, káláàmù,.....
Yàtò sí Òrò àyálò, gbogbo Òrò orúko ló bèrè pèlú fáwèlì.
Sùgbón bí ó ti wù kí ó jé, Òrò-orúko jé Òrò tí a fi ń pé nńkan kan pàtó.
A lè pín Òrò orúko sí orísirísi òwó; èyí tó ń tóka sí èèyàn, eranko, nńkan abèmí, nńkan aláìléèmí, àfòyemò, ibi, ònkà àti bęè bęè lo.....
A ó ma tè síwájú lósè tí ń bò. Ire ó!

Comments

Post a Comment

Popular posts from this blog

Gírámà èdè Yorùbá: Òrò Atókùn (prepositions)

Gírámà èdè Yorùbá; Èyán (Adjective)

Ęwààtoge: Orísirísi fìlà okùnrin ní ilè Yorùbá. Beauty&style (types of caps among Yorùbá men).