Contemporary music with Yorùbá lyrics (Orin ìgbàlódé tó kún fún èdè Yorùbá)


Láti ìgbà tí Olódùmarè ti sèdá ènìyàn ni ó ti fún won ní ohùn àti ogbòn ìlò ohùn láti máa fi èrò inú won han elòmíràn, yóò tètè yé wa irú ipò pàtàkì tí ìlò ohùn kó ní àwùjo. Bí àwùjo kan bá jé àwùjo sòròsòrò bí i ti Yorùbá, a óò rii pé láti ilè pèpè ni Olódùmarè tí fún won ní irin isé Òrò siso. Ó ro àwon Yorùbá lórùn púpò láti máa fi Òrò enu won àti ohùn won dá orísirísi àrà láti fí èrò inú won hàn, kò sí itú tí won ń fi èdè pa, yálà nínú Òrò geere, nínú ewì tàbí Orin kíko.
 
Akíyèsí wa ni wí pé kí èèyàn tó lè korin tó mógbón wa tàbí ko Orin tí ń kóni léèkó,yálà èkó èdè ni, ìwà omolúàbí, àsà tàbí orin ìláforítì a.b.b.l. Ó gbúdò jé eni tó ní ìrònú tó jinlè tí opolo rè sí pé dáada. Torí wí pé àtàrí àjànàkú ni isé Orin kíko, kìí se erù omodé. Ìdí nìyìí tí a fi gbé abala yìí kalè láti máa gbóríyìn fún àwon akorin tí ń ló èdè àbínibí Yorùbá nínú Orin won.

Olórin tí à ó máa Se àgbéyèwò orin rè lóní ni @qdot_alagbe. Tí a bá ń so ní pa ká korin tó kún fún èdòki Òrò Yorùbá tàbí kí a korin tí ń gbásà àti èdè Yorùbá láruge láwùjo wa lóní, òkan gbòógì ní @qdot_alagbe jé nínú àwon ojúlówó Omo Yorùbá tí ń fí èdè Yorùbá yangàn nínú Orin rè.
Òpòlopò Orin ló tí ko tó kún fún Òrò Yorùbá sùgbón eyìí tí a nífé sí jù ló ní
#ijógèlèdè
 #lálalù
#apalanewskool
#Ààre. a.b.b.l
Kó sí ani-àní wí pé omo Òduà tokàntokàn ní @qdot_alagbe jé
Èdùmàrè yóò tún bò máa kún yín lówó,
opolo yín kò ní jóbà,
sèkèrè kìí ròde ìbánújé, Ę ò ní ròde ìbánújé,
 iwájú lòpá èbìtì yín yóò ma ré sí.
Àse!

Comments

Popular posts from this blog

Gírámà èdè Yorùbá: Òrò Atókùn (prepositions)

Gírámà èdè Yorùbá; Èyán (Adjective)

Ęwààtoge: Orísirísi fìlà okùnrin ní ilè Yorùbá. Beauty&style (types of caps among Yorùbá men).