Ęwà àtoge (Àsà ìwoso okùnrin nílè Yorùbá) Beauty&style.

Gégé bí a ti so lósè to kojá wí pé, òdú ni Òrò ęwà àtoge síse jé ní ìran Yorùbá kìí se àìmò fólóko won, sáájú kí òlàjú àwon òyìnbó tó wo àwùjo Yorùbá ni wón tí ní orísirísi ònà tí wón gbà sęwà àtoge láàárin tèwe tàgbà, Okùnrin àti obìnrin, Ojúùwòye won ní pa oge síse àtęwà síse ní pé 'ìrínisí ni ìseni lójò àti wí pé bí èèyàn bá se mo ìtójú ara rè se ní yóò se mo ìtójú nńkan rè se sí.

    Kò sí tàbí sùgbón níbè wí pé Yorùbá jé ìran tó ní afínjú, Wón gbáfé, àti wí pé won kò sí fojú rénà àsà ìwoso won. Bí a bá ń so ní pa ká soge láàárin àwon okùnrin ní ilè Yorùbá, kìí se ohun tó níye lórí lo títí, Torí Yorùbá gbà wí pé alàì-ní-nńkan se okùnrin níì má ń jí gbó toge.
 Fún Ìdí èyí orísi aso tí okùnrin ní nílè Yorùbá kò ju Mérin péré lo,
Àwon ni Sòkòtò, Bùbá, Agbádá àti Fìlà.
A ó ma tè síwájú lósè tí ń bò. Ire ó!

Comments

Popular posts from this blog

Gírámà èdè Yorùbá: Òrò Atókùn (prepositions)

Gírámà èdè Yorùbá; Èyán (Adjective)

Ęwààtoge: Orísirísi fìlà okùnrin ní ilè Yorùbá. Beauty&style (types of caps among Yorùbá men).