Ìfáàrà sí gírámà èdè Yorùbá.


Ó se pàtàkì kí a mò wí pé kìí se pé a ń gbé elédè jókòó láti kó ní èdè rè, Torí Elédùmarè ti da èdè mó Èèyàn bí ó ti dá mèéè mó àgùntàn, tí ó sì dá kekeréńke mó akùko. Eyìí ni pe èèyàn mú ìmò èdè wá látòrun ni, ìmò àbínibí yìí ni èèyàn fi ń jé èèyàn, gbogbo  èdè la lè so sùgbón eyìí tí aládùgbò wa bá gbó ni a ń so nígbèyìn. Ìdí nìyìí tí Omo Yorùbá tí a bí ní ìlú òyìnbó yóò fi gbó Gèésì bí oba ìlú Èèbó. Béè sì ni Omo Hawusa tí a bí ní Ilé-ifè yóò lè so Yorùbá bí Omo Ooni. Ìdí nìyìí tí ó fi jé pé bí omodé bá ń dàgbà láàárin orísirísi èyà yóò gbó òpò èdè.

Ohun tí a o gbájú mó níbí abala yìí ni ohun tí elédè gbudò mò kí a tó so pé ó gbó èdè náà. Nnkan yìí lè jé àtòpò Ìrò ní ìbámu pèlú ìlànà kan pàtó, Ó lè jé àtòpò orísirísi Òrò, Ó sì lè jé orísi ìtumò ti àtòpò ìró ohùn tàbí àtòpò Òrò ní.
   Ìmò èdè jé ìmò nípa ìró, Òrò àti ìtumò won nínú àtòpò. Ní ònà míràn èwè, ìmò èdè tí a ń pé ní gírámà pín sí orísi méta pàtàkì;  ìró ohùn (ìmò fònétíìkì), àtòpò Òrò (ìmò síntáàsì) àti ìtumò (ìmò sèmántìíkì).
A Ó ma tè síwájú lósè tí ń bò. Ire o!

Comments

Popular posts from this blog

Gírámà èdè Yorùbá: Òrò Atókùn (prepositions)

Gírámà èdè Yorùbá; Èyán (Adjective)

Ęwààtoge: Orísirísi fìlà okùnrin ní ilè Yorùbá. Beauty&style (types of caps among Yorùbá men).